8. Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ.
9. Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.
10. Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe,
11. Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní.
12. Ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse, ni Joṣua wipe,