6. Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.
7. Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ.
8. Iwé ofin yi kò gbọdọ kuro li ẹnu rẹ, ṣugbọn iwọ o ma ṣe àṣaro ninu rẹ̀ li ọsán ati li oru, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti a kọ sinu rẹ̀: nitori nigbana ni iwọ o ṣe ọ̀na rẹ ni rere, nigbana ni yio si dara fun ọ.
9. Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.
10. Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe,
11. Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní.