8. Bawo li ẹnyin ṣe wipe, Ọlọgbọ́n ni wa, ati ofin Oluwa mbẹ lọdọ wa? sa wò o nitõtọ! kalamu eke awọn akọwe ti sọ ofin di eke.
9. Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn?
10. Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.
11. Nitoripe nwọn ti wo ipalara ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀ wipe, Alafia! Alafia! nigbati alafia kò si.