50. Ẹnyin ti o ti bọ lọwọ idà, ẹ lọ, ẹ má duro: ẹ ranti Oluwa li okere, ẹ si jẹ ki Jerusalemu wá si ọkàn nyin.
51. Oju tì wa, nitoripe awa ti gbọ́ ẹ̀gan: itiju ti bò loju, nitori awọn alejo wá sori ohun mimọ́ ile Oluwa.
52. Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o ṣe ibẹwo lori awọn ere fifin rẹ̀: ati awọn ti o gbọgbẹ yio si mã gbin ja gbogbo ilẹ rẹ̀.
53. Bi Babeli tilẹ goke lọ si ọrun, bi o si ṣe olodi li oke agbara rẹ̀, sibẹ awọn afiniṣeijẹ yio ti ọdọ mi tọ̀ ọ wá, li Oluwa wi.
54. Iró igbe lati Babeli! ati iparun nla lati ilẹ awọn ara Kaldea!
55. Nitoripe Oluwa ti ṣe Babeli ni ijẹ, o si ti pa ohùn nla run kuro ninu rẹ̀; riru wọn si nho bi omi pupọ, a gbọ́ ariwo ohùn wọn.
56. Nitoripe afiniṣeijẹ de sori rẹ̀, ani sori Babeli; a mu awọn akọni rẹ̀, a ṣẹ́ gbogbo ọrun wọn: nitori Ọlọrun ẹsan ni Oluwa, yio san a nitõtọ.
57. Emi o si mu ki awọn ijoye rẹ̀ yo bi ọ̀muti, ati awọn ọlọgbọn rẹ̀, awọn bàlẹ rẹ̀, ati awọn alakoso rẹ̀, ati awọn akọni rẹ̀, nwọn o si sun orun lailai, nwọn kì o si ji mọ́, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun.
58. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: odi Babeli gbigboro li a o wó lulẹ patapata, ẹnu-bode giga rẹ̀ li a o si fi iná sun: tobẹ̃ ti awọn enia ti ṣiṣẹ lasan, ati awọn orilẹ-ède ti ṣiṣẹ fun iná, ti ãrẹ si mu wọn.
59. Ọ̀rọ ti Jeremiah woli paṣẹ fun Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maaseiah, nigbati o nlọ niti Sedekiah, ọba Judah, si Babeli li ọdun kẹrin ijọba rẹ̀. Seraiah yi si ni ijoye ibudo.