Jer 50:7-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Gbogbo awọn ti o ri wọn, ti pa wọn jẹ: awọn ọta wọn si wipe, Awa kò jẹbi, nitoripe nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awọn baba wọn, ani Oluwa.

8. Ẹ salọ kuro li ãrin Babeli, ẹ si jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, ki ẹ si jẹ bi obukọ niwaju agbo-ẹran.

9. Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.

10. Kaldea yio si di ikogun: gbogbo awọn ti o fi ṣe ikogun ni a o tẹ́ lọrùn, li Oluwa wi.

Jer 50