Jer 50:14-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ẹ tẹgun si Babeli yikakiri: gbogbo ẹnyin ti nfà ọrun, ẹ tafa si i, ẹ máṣe ṣọ́ ọfa lò, nitoriti o ti ṣẹ̀ si Oluwa.

15. Ẹ ho bo o yikakiri: o ti nà ọwọ rẹ̀: ọwọ̀n ìti rẹ̀ ṣubu, a wó odi rẹ̀ lulẹ: nitori igbẹsan Oluwa ni: ẹ gbẹsan lara rẹ̀; gẹgẹ bi o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i.

16. Ke afunrugbin kuro ni Babeli, ati ẹniti ndi doje mu ni igbà ikore! nitori ẹ̀ru idà ti nṣika, olukuluku wọn o yipada si ọdọ enia rẹ̀, olukuluku yio si salọ si ilẹ rẹ̀.

17. Israeli jẹ́ agutan ti o ṣina kiri, awọn kiniun ti le e lọ: niṣaju ọba Assiria pa a jẹ, ati nikẹhin yi Nebukadnessari, ọba Babeli, sán egungun rẹ̀.

18. Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o jẹ ọba Babeli ati ilẹ rẹ̀ niya, gẹgẹ bi emi ti jẹ ọba Assiria niya.

19. Emi o si tun mu Israeli wá si ibugbe rẹ̀, on o si ma bọ ara rẹ̀ lori Karmeli, ati Baṣani, a o si tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrun li oke Efraimu ati ni Gileadi.

Jer 50