Jer 46:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ẽṣe ti emi ti ri wọn ni ibẹ̀ru ati ni ipẹhinda? awọn alagbara wọn li a lù bolẹ, nwọn sa, nwọn kò si wò ẹhin: ẹ̀ru yika kiri, li Oluwa wi.

6. Ẹni ti o yara, kì yio salọ, alagbara ọkunrin kì yio si sala: ni iha ariwa lẹba odò Ferate ni nwọn o kọsẹ̀, nwọn o si ṣubu.

7. Tani eyi ti o goke wá bi odò, ti omi rẹ̀ nrú gẹgẹ bi odò wọnni?

8. Egipti dide bi odò Nile, omi rẹ̀ si nrú bi omi odò wọnni; o si wipe, Emi o goke lọ, emi o si bò ilẹ aiye, emi o si pa ilu ati awọn olugbe inu rẹ̀ run!

9. Ẹ goke wá, ẹnyin ẹṣin, ẹ si sare kikan, ẹnyin kẹ̀kẹ; ki awọn alagbara si jade wá; awọn ara Etiopia, ati awọn ara Libia, ti o ndi asà mu; ati awọn ara Lidia ti nmu ti o nfa ọrun.

10. Ṣugbọn ọjọ yi li ọjọ igbẹsan Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ki o le gbẹsan lara awọn ọta rẹ̀; idà yio si jẹ, yio si tẹ́ ẹ lọrun, a o si fi ẹ̀jẹ wọn mu u yo: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni irubọ ni ilẹ ariwa lẹba odò Euferate.

Jer 46