Jer 44:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá fun gbogbo awọn ara Juda ti ngbe ilẹ Egipti, ti ngbe Migdoli, ati Tafanesi, ati Nofu, ati ilẹ Patrosi, wipe,

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, ẹnyin ti ri gbogbo ibi ti emi ti mu wá sori Jerusalemu, ati sori gbogbo ilu Juda; si wò o, ahoro ni nwọn li oni yi, ẹnikan kò si gbe inu wọn.

3. Nitori ìwa-buburu wọn ti nwọn ti hú lati mu mi binu, ni lilọ lati sun turari ati lati sìn awọn ọlọrun miran, ti nwọn kò mọ̀, awọn, tabi ẹnyin, tabi awọn baba nyin.

4. Emi si ran gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli si nyin, emi dide ni kutukutu, mo rán wọn, wipe, A! ẹ máṣe ohun irira yi ti emi korira.

5. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò tẹti wọn silẹ lati yipada kuro ninu ìwa-buburu wọn, ki nwọn ki o má sun turari fun ọlọrun miran.

6. Nitorina ni mo ṣe dà ìrunu mi ati ibinu mi jade, a si daná rẹ̀ ni ilu Juda, ati ni ita Jerusalemu: nwọn si di ofo ati ahoro, gẹgẹ bi ti oni yi.

7. Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, nitori kini ẹ ṣe da ẹ̀ṣẹ nla yi si ọkàn nyin, lati ke ninu nyin ani ọkunrin ati obinrin, ati ọmọde ati ọmọ-ọmu, kuro lãrin Juda, lati má kù iyokú fun nyin;

8. Ninu eyiti ẹnyin fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, ni sisun turari fun ọlọrun miran ni ilẹ Egipti, nibiti ẹnyin lọ lati ṣatipo, ki ẹ le ke ara nyin kuro, ati ki ẹ le jẹ ẹni-ègun ati ẹsin, lãrin gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye?

Jer 44