Jer 41:4-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. O si ṣe li ọjọ keji lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ti ẹnikan kò si mọ̀.

5. Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.

6. Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu.

7. O si ṣe, nigbati nwọn de ãrin ilu, ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, pa wọn, on, ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀ si sọ wọn sinu iho.

8. Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.

Jer 41