12. Ebedmeleki, ara Etiopia, si sọ fun Jeremiah pe, Fi akisa ati oṣuka wọnyi si abẹ abia rẹ, lori okùn. Jeremiah si ṣe bẹ̃.
13. Bẹ̃ni nwọn fi okùn fà Jeremiah soke, nwọn si mu u goke lati inu iho wá: Jeremiah si wà ni agbala ile-tubu.
14. Nigbana ni Sedekiah, ọba, ranṣẹ, o mu Jeremiah woli, wá sọdọ rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na kẹta ti o wà ni ile Oluwa: ọba si wi fun Jeremiah pe, Emi o bi ọ lere ohun kan: máṣe fi nkankan pamọ fun mi.
15. Jeremiah si wi fun Sedekiah pe, Bi emi ba sọ fun ọ, iwọ kì o ha pa mi nitõtọ? bi mo ba si fi imọran fun ọ, iwọ kì yio fetisi ti emi.
16. Sedekiah, ọba, si bura nikọkọ fun Jeremiah, wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹni ti o da ẹmi wa yi, emi kì yio pa ọ, bẹ̃ni emi kì yio fi ọ le ọwọ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwá ẹmi rẹ.
17. Nigbana ni Jeremiah sọ fun Sedekiah pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe: Bi iwọ o ba jade nitõtọ tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni ọkàn rẹ yio yè, a ki yio si fi iná kun ilu yi; iwọ o si yè ati ile rẹ.
18. Ṣugbọn bi iwọ kì yio ba jade tọ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni a o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, nwọn o si fi iná kun u, iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn.
19. Sedekiah ọba, si sọ fun Jeremiah pe, Ẹ̀ru awọn ara Juda ti o ya tọ awọn ara Kaldea mbà mi, ki nwọn ki o má ba fi mi le wọn lọwọ; nwọn a si fi mi ṣẹsin.
20. Ṣugbọn Jeremiah wipe, nwọn kì yio si fi ọ le wọn lọwọ, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa ti mo sọ fun ọ: yio si dara fun ọ, ọkàn rẹ yio si yè.