Jer 36:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O si ṣe li ọdun karun Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, li oṣu kẹsan ni nwọn kede ãwẹ niwaju Oluwa, fun gbogbo enia ni Jerusalemu: ati fun gbogbo awọn enia ti o wá lati ilu Juda, si Jerusalemu.

10. Baruku si ka ọ̀rọ Jeremiah lati inu iwe ni ile Oluwa, ni iyara Gemariah, ọmọ Ṣafani, akọwe, ni àgbala oke, nibi ilẹkun ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa li eti gbogbo enia.

11. Nigbati Mikaiah, ọmọ Gemariah, ọmọ Ṣafani, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Oluwa lati inu iwe na wá,

12. O si sọkalẹ lọ si ile ọba, sinu iyara akọwe, si wò o, gbogbo awọn ijoye joko nibẹ, Eliṣama, akọwe, ati Delaiah, ọmọ Semaiah, ati Elnatani, ọmọ Akbori, ati Gemariah, ọmọ Safani, ati Sedekiah, ọmọ Hananiah, ati gbogbo awọn ijoye.

13. Nigbana ni Mikaiah sọ gbogbo ọ̀rọ wọnni ti o ti gbọ́, fun wọn, nigbati Baruku kà lati inu iwe na li eti awọn enia.

Jer 36