5. Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini.
6. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio mu ọti-waini, nitori Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa, paṣẹ fun wa pe: Ẹnyin kò gbọdọ mu ọti-waini, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin lailai.
7. Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ kọ́ ile, tabi ki ẹ fun irugbin, tabi ki ẹ gbin ọgba-àjara, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ni; ṣugbọn ni gbogbo ọjọ nyin li ẹnyin o ma gbe inu agọ; ki ẹnyin ki o le wà li ọjọ pupọ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nṣe atipo.
8. Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa;
9. Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin.
10. Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa.