7. Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju.
8. Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi.
9. Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u.