5. On o si mu Sedekiah lọ si Babeli, nibẹ ni yio si wà titi emi o fi bẹ̀ ẹ wò, li Oluwa wi; bi ẹnyin tilẹ ba awọn ará Kaldea jà, ẹnyin kì yio ṣe rere.
6. Jeremiah si wipe, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,
7. Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a.
8. Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.
9. Emi si rà oko na lọwọ Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ti o wà ni Anatoti, mo si wọ̀n owo fun u, ṣekeli meje ati ìwọn fadaka mẹwa.