38. Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti a o kọ́ ilu na fun Oluwa lati ile-iṣọ Hananeeli de ẹnu-bode igun odi.
39. Okùn ìwọn yio si nà jade siwaju lẹba rẹ̀ lori oke Garebi, yio si lọ yi Goati ka.
40. Ati gbogbo afonifoji okú, ati ti ẽru, ati gbogbo oko titi de odò Kidroni, titi de igun ẹnubode-ẹṣin niha ilà-õrun, ni yio jẹ mimọ́ fun Oluwa; a kì yio fà a tu, bẹ̃ni a kì yio si wó o lulẹ mọ lailai.