Jer 29:1-2 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI si li ọ̀rọ iwe ti Jeremiah woli rán lati Jerusalemu si iyokù ninu awọn àgba ti o wà ni igbèkun, ati si awọn alufa, ati awọn woli, ati si gbogbo enia ti Nebukadnessari kó ni igbekun lọ lati Jerusalemu si Babeli.

2. Lẹhin igbati Jekoniah, ọba, ati ayaba, ati awọn iwẹfa, ati awọn ijoye Juda ati Jerusalemu, ati awọn gbẹna-gbẹna pẹlu awọn alagbẹdẹ ti fi Jerusalemu silẹ lọ.

Jer 29