12. Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè.
13. Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli.
14. Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
15. Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.