Jer 24:3-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù.

4. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea.

6. Emi o si kọju mi si wọn fun rere, emi o si mu wọn pada wá si ilẹ yi, emi o gbe wọn ró li aitun wó wọn lulẹ, emi o gbìn wọn, li aitun fà wọn tu.

7. Emi o si fun wọn li ọkàn lati mọ̀ mi, pe, Emi li Oluwa, nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nitoripe nwọn o fi gbogbo ọkàn wọn yipada si mi.

Jer 24