1. SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli.
2. Agbọn ikini ni eso-ọ̀pọtọ daradara jù, gẹgẹ bi eso ọ̀pọtọ ti o tetekọ pọ́n: agbọn ekeji ni eso-ọ̀pọtọ ti o buruju, ti a kò le jẹ, bi nwọn ti buru tó.