21. Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ.
22. Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ.
23. Iwọ, olugbe Lebanoni, ti o tẹ́ itẹ si ori igi kedari, iwọ o ti jẹ otoṣi to, nigbati irora ba deba ọ, irora bi obinrin ti nrọbi!
24. Bi emi ti wà, li Oluwa wi, bi Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, tilẹ jẹ oruka-èdidi lọwọ ọtun mi, sibẹ̀ emi o fà ọ tu kuro nibẹ.
25. Emi o si fi ọ le ọwọ awọn ti o nwá ẹmi rẹ, ati le ọwọ ẹniti iwọ bẹ̀ru rẹ̀, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati ọwọ awọn ara Kaldea.
26. Emi o tì ọ sode, ati iya rẹ ti o bi ọ si ilẹ miran, nibiti a kò bi nyin si; nibẹ li ẹnyin o si kú.
27. Ṣugbọn ilẹ na ti ẹnyin fẹ li ọkàn nyin lati pada si, nibẹ ni ẹnyin kì o pada si mọ.