Jer 20:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ Paṣuri, ọmọ Immeri, alufa, ti iṣe olori olutọju ni ile Oluwa, gbọ́ pe, Jeremiah sọ asọtẹlẹ ohun wọnyi.

2. Nigbana ni Paṣuri lù Jeremiah, woli, o si kàn a li àba ti o wà ni ẹnu-ọ̀na Benjamini, ti o wà li òke ti o wà lẹba ile Oluwa.

3. O si ṣe ni ọjọ keji, Paṣuri mu Jeremiah kuro ninu àba. Nigbana ni Jeremiah wi fun u pe, Oluwa kò pe orukọ rẹ ni Paṣuri (ire-yika-kiri), bikoṣe Magori-missa-bibu (idãmu-yika-kiri.)

Jer 20