6. Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.
7. Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:
8. Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.
9. Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà.
10. Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ?
11. Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè.
12. Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi!
13. Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.
14. Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibile? ẽṣe ti o fi di ijẹ.
15. Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe.
16. Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ;
17. Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na?
18. Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀.
19. Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kò Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.
20. Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga.
21. Ṣugbọn emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata: ẽṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi?