1. Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin.
2. Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin.
3. Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin.
4. Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun.