Jak 2:20-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ṣugbọn, iwọ alaimoye enia, iwọ ha fẹ mọ̀ pe, igbagbọ́ li aisi iṣẹ asan ni?

21. Kì ha iṣe nipa iṣẹ li a dá Abrahamu baba wa lare, nigbati o fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rubọ lori pẹpẹ?

22. Iwọ ri pe igbagbọ́ bá iṣẹ rẹ̀ rìn, ati pe nipa iṣẹ li a sọ igbagbọ́ di pipé.

23. Iwe-mimọ́ si ṣẹ ti o wipe, Abrahamu gbà Ọlọrun gbọ́, a si kà a si ododo fun u: a si pè e li ọ̀rẹ́ Ọlọrun.

24. Njẹ ẹnyin ri pe nipa iṣẹ li a ndá enia lare, kì iṣe nipa igbagbọ́ nikan.

25. Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran?

26. Nitori bi ara li aisi ẹmí ti jẹ́ okú, bẹ̃ gẹgẹ pẹlu ni igbagbọ́ li aisi iṣẹ jẹ́ okú.

Jak 2