23. Nitori bi ẹnikan ba jẹ olugbọ́ ọ̀rọ na, ti kò si jẹ oluṣe, on dabi ọkunrin ti o nṣakiyesi oju ara rẹ̀ ninu awojiji:
24. Nitori o ṣakiyesi ara rẹ̀, o si ba tirẹ̀ lọ, lojukanna o si gbagbé bi on ti ri.
25. Ṣugbọn ẹniti o ba nwo inu ofin pipé, ofin omnira nì, ti o si duro ninu rẹ̀, ti on kò jẹ olugbọ́ ti ngbagbé, bikoṣe oluṣe iṣẹ, oluwarẹ̀ yio jẹ alabukun ninu iṣẹ rẹ̀.
26. Bi ẹnikẹni ba ro pe on nsìn Ọlọrun nigbati kò kó ahọn rẹ̀ ni ijanu, ṣugbọn ti o ntàn ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsin oluwarẹ̀ asan ni.