8. Yio si kọja li arin Juda; yio si ṣàn bò o mọlẹ yio si mù u de ọrùn, ninà iyẹ rẹ̀ yio si kún ibú ilẹ rẹ, iwọ Immanueli.
9. Ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin enia, a o si fọ nyin tũtu: ẹ si fi eti silẹ, gbogbo ẹnyin ará ilẹ jijìna: ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu; ẹ di ara nyin li àmure, a o si fọ nyin tũtu.
10. Ẹ gbìmọ pọ̀ yio si di asan; ẹ sọ̀rọ na, ki yio si duro: nitoripe Ọlọrun wà pẹlu wa.
11. Nitoriti Oluwa wi bayi fun mi, nipa ọwọ agbara, o si kọ mi ki nmá ba rìn ni ọ̀na enia yi, pe,
12. Ẹ máṣe pè gbogbo eyi ni imulẹ ti awọn enia yi pè ni imulẹ: bẹ̃ni ẹ máṣe bẹ̀ru ibẹ̀ru wọn, ẹ má si ṣe foya.
13. Yà Oluwa awọn ọmọ-ogun tikalarẹ̀ si mimọ́; si jẹ ki o ṣe ẹ̀ru nyin, si jẹ ki o ṣe ifòya nyin.
14. On o si wà fun ibi mimọ́, ṣugbọn fun okuta idùgbolu, ati fun apata ẹ̀ṣẹ, si ile Israeli mejeji, fun ẹgẹ, ati fun okùn didẹ si awọn ara Jerusalemu.