Isa 7:20-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Li ọjọ kanna ni Oluwa yio fi abẹ ti a yá, eyini ni, awọn ti ihà keji odo nì, ọba Assiria, fá ori ati irun ẹsẹ, yio si run irungbọn pẹlu.

21. Yio si ṣe li ọjọ na, enia kan yio si tọ́ ọmọ malu kan ati agutan meji;

22. Yio si ṣe, nitori ọ̀pọlọpọ wàra ti nwọn o mu wá, yio ma jẹ ori-amọ; nitori ori-amọ ati oyin ni olukulùku ti o ba kù ni ãrin ilẹ na yio ma jẹ.

23. Yio si ṣe li ọjọ na, ibi gbogbo yio ri bayi pe, ibi ti ẹgbẹrun àjara ti wà fun ẹgbẹrun owo fadakà yio di ti ẹwọn ati ẹgun.

24. Pẹlu ọfà ati ọrun ni enia yio wá ibẹ, nitoripe gbogbo ilẹ na yio di ẹwọn ati ẹgun.

Isa 7