12. Nitori orilẹ-ède, tabi ilẹ ọba ti kì yio sin ọ, yio ṣegbe; orilẹ-ède wọnni li a o sọ dahoro raurau.
13. Ogo Lebanoni yio wá sọdọ rẹ, igi firi, igi pine, pẹlu igi boksi, lati ṣe ibi mimọ́ mi li ọṣọ; emi o ṣe ibi ẹsẹ mi logo.
14. Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli.
15. Ni bi a ti kọ̀ ọ silẹ, ti a si ti korira rẹ, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja lãrin rẹ, emi o sọ ọ di ogo aiyeraiye, ayọ̀ iran-de-iran ọ̀pọlọpọ.
16. Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu.
17. Nipo idẹ emi o mu wura wá, nipo irin emi o mu fadaka wá, ati nipo igi, idẹ, ati nipo okuta, irin: emi o ṣe awọn ijoye rẹ ni alafia, ati awọn akoniṣiṣẹ́ rẹ ni ododo.
18. A kì yio gbọ́ ìwa-ipá mọ ni ilẹ rẹ, idahoro tabi iparun li agbègbe rẹ; ṣugbọn iwọ o pe odi rẹ ni Igbala, ati ẹnu-bodè rẹ ni Iyin.
19. Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ.
20. Õrùn rẹ ki yio wọ̀ mọ; bẹ̃ni oṣupa rẹ kì yio wọ̃kùn: nitori Oluwa yio jẹ imọlẹ ainipẹkun fun ọ, ọjọ ãwẹ̀ rẹ wọnni yio si de opin.
21. Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo.
22. Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.