3. Mo fi ohun dúdu wọ̀ awọn ọrun, mo si fi aṣọ ọfọ̀ ṣe ibora wọn.
4. Oluwa Jehofa ti fi ahọn akẹ́kọ fun mi, ki emi ki o le mọ̀ bi a iti sọ̀rọ li akokò fun alãrẹ, o nji li oròwurọ̀, o ṣi mi li eti lati gbọ́ bi akẹkọ.
5. Oluwa Jehofa ti ṣí mi li eti, emi kò si ṣe aigbọràn, bẹ̃ni emi kò yipada.
6. Mo fi ẹ̀hìn mi fun awọn aluni, ati ẹ̀rẹkẹ mi fun awọn ti ntú irun: emi kò pa oju mi mọ́ kuro ninu itìju ati itutọ́ si.
7. Nitori Oluwa Jehofa yio ràn mi lọwọ: nitorina emi kì yio dãmu; nitorina ni mo ṣe gbe oju mi ró bi okuta lile, emi si mọ̀ pe oju kì yio tì mi.
8. Ẹniti o dá mi lare wà ni tosí, tani o ba mi jà? jẹ ki a duro pọ̀: tani iṣe ẹlẹ́jọ mi? jẹ ki o sunmọ mi.