1. BAYI ni Oluwa wi fun ẹni-ororo rẹ̀, fun Kirusi, ẹniti mo di ọwọ́ ọtún rẹ̀ mu, lati ṣẹ́gun awọn orilẹ-ède niwaju rẹ̀; emi o si tú amure ẹgbẹ awọn ọba, lati ṣi ilẹkùn mejeji niwaju rẹ̀, a ki yio si tì ẹnu-bode na;
2. Emi o lọ siwaju rẹ, emi o si sọ ibi wiwọ́ wọnni di titọ́: emi o fọ ilẹkùn idẹ wọnni tũtũ, emi o si ke ọjá-irin si meji.
3. Emi o si fi iṣura okùnkun fun ọ, ati ọrọ̀ ti a pamọ nibi ikọkọ, ki iwọ le mọ̀ pe, emi Oluwa, ti o pè ọ li orukọ rẹ, li Ọlọrun Israeli.