Isa 42:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.

14. Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna.

15. Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ.

16. Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.

17. A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.

18. Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i.

19. Tani afọju, bikoṣe iranṣẹ mi? tabi aditi, bi ikọ̀ mi ti mo rán? tani afọju bi ẹni pipé? ti o si fọju bi iranṣẹ Oluwa?

20. Ni riri nkan pupọ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi i; ni ṣiṣi eti, ṣugbọn on ko gbọ́.

21. Inu Oluwa dùn gidigidi nitori ododo rẹ̀; yio gbe ofin ga, yio si sọ ọ di ọlọlá.

Isa 42