Isa 36:20-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Tani ninu gbogbo oriṣa ilẹ wọnyi, ti o ti gbà ilẹ wọn kuro li ọwọ́ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro li ọwọ́ mi?

21. Ṣugbọn nwọn dakẹ, nwọn kò si da a lohùn ọ̀rọ kan: nitoriti aṣẹ ọba ni, pe, Ẹ máṣe da a lohùn.

22. Nigbana ni Eliakimu, ọmọ Hilkia, ti iṣe olutọju ile, ati Ṣebna akọwe, ati Joa, ọmọ Asafu akọwe iranti, wá sọdọ Hesekiah ti awọn ti aṣọ wọn ni fifàya, nwọn si sọ ọ̀rọ Rabṣake fun u.

Isa 36