21. Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja.
22. Nitori Oluwa ni onidajọ wa, Oluwa li olofin wa, Oluwa li ọba wa; on o gbà wa là.
23. Okùn opó-ọkọ̀ rẹ tú; nwọn kò le dì opó-ọkọ̀ mu le danin-danin, nwọn kò le ta igbokun: nigbana li a pin ikogun nla; amúkun ko ikogun.
24. Ati awọn ará ibẹ̀ ki yio wipe, Ara mi kò yá: a o dari aiṣedede awọn enia ti ngbe ibẹ jì wọn.