6. Nitori eniakenia yio ma sọ isọkusọ, ọkàn rẹ̀ yio si ma ṣiṣẹ aiṣedede, lati ṣe agabàgebe, ati lati ṣì ọ̀rọ sọ si Oluwa, lati sọ ọkàn ẹniti ebi npa di ofo, ati lati mu ki ohun-mimu awọn ti ongbẹ ngbẹ ki o dá.
7. Ibi ni gbogbo ohun-elò enia-kenia jẹ pẹlu: on gbà èro buburu, lati fi ọ̀rọ eke pa talaka run, bi alaini tilẹ nsọ õtọ ọ̀rọ.
8. Ṣugbọn ẹni-rere a ma gbèro ohun rere; nipa ohun-rere ni yio ṣe duro.
9. Dide, ẹnyin obinrin ti o wà ni irọra; gbọ́ ohùn mi, ẹnyin alafara obinrin; fetisi ọ̀rọ mi.
10. Ọpọlọpọ ọjọ, on ọdún, li a o fi ma wahala nyin, ẹnyin alafara obinrin: nitori ikore kì yio si, kikojọ rẹ̀ kì yio de.