Isa 29:14-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.

15. Egbe ni fun awọn ti nwá ọ̀na lati fi ipinnu buruburu wọn pamọ́ kuro loju Oluwa, ti iṣẹ wọn si wà li okunkun, ti nwọn si wipe, Tali o ri wa? tali o mọ̀ wa?

16. A, iyipo nyin! a ha le kà amọ̀koko si bi amọ̀: ohun ti a mọ ti ṣe lè wi fun ẹniti o ṣe e pe, On kò ṣe mi? ìkoko ti a mọ le wi fun ẹniti o mọ ọ pe, On kò moye?

17. Kò ha ṣe pe ìgba diẹ kiun si i, a o sọ Lebanoni di ọgbà eleso, ati ọgbà eleso li a o kà si bi igbo?

18. Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun.

19. Ayọ̀ awọn onirẹlẹ yio bí si i ninu Oluwa, ati inu awọn talaka ninu awọn enia yio si dùn ninu Ẹni-Mimọ Israeli.

20. Nitori a sọ aninilara na di asan, a si pa ẹlẹgàn run, a si ké gbogbo awọn ti nṣọ́ aiṣedede kuro.

21. Ẹniti o dá enia li ẹbi nitori ọ̀rọ kan, ti nwọn dẹkùn silẹ fun ẹniti o baniwi ni ẹnubodè, ti nwọn si tì olododo si apakan, si ibi ofo.

22. Nitorina bayi li Oluwa, ẹniti o rà Abrahamu padà wi, pe, niti ile Jakobu, oju kì yio tì Jakobu mọ bẹ̃ni oju rẹ̀ kì yio yipada mọ.

23. Ṣugbọn nigbati on nri awọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ ọwọ́ mi, li ãrin rẹ̀, nwọn o yà orukọ mi si mimọ́, nwọn o si yà Ẹni-Mimọ Jakobu nì si mimọ́, nwọn o si bẹ̀ru Ọlọrun Israeli.

Isa 29