14. Hu, ẹnyin ọkọ̀ Tarṣiṣi: nitori a sọ agbara nyin di ahoro.
15. Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbagbe Tire li ãdọrin ọdun, gẹgẹ bi ọjọ ọba kan: lẹhin ãdọrin ọdun ni Tire yio kọrin bi panṣaga obinrin.
16. Mu harpu kan, kiri ilu lọ, iwọ panṣaga obinrin ti a ti gbagbe; dá orin didùn: kọ orin pupọ̀ ki a le ranti rẹ.
17. Yio si ṣe li ẹhìn ãdọrin ọdun, ni Oluwa yio bẹ̀ Tire wò, yio si yipadà si ọ̀ya rẹ̀, yio si ba gbogbo ijọba aiye yi ti o wà lori ilẹ ṣe àgbere.