1. Ọ̀RỌ-ìmọ niti ijù okun. Gẹgẹ bi ãja gusù ti ikọja lọ; bẹ̃ni o ti ijù wá, lati ilẹ ti o li ẹ̀ru.
2. Iran lile li a fi hàn mi; ọ̀dalẹ dalẹ, akoni si nkoni. Goke lọ, iwọ Elamu: dotì, iwọ Media; gbogbo ìmí-ẹ̀dùn inu rẹ̀ li emi ti mu da.
3. Nitorina ni ẹgbẹ́ mi ṣe kun fun irora: irora si ti dì mi mu, gẹgẹ bi irora obinrin ti nrọbi: emi tẹ̀ ba nigbati emi gbọ́ ọ: emi dãmu nigbati emi ri i.