Isa 2:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe.

9. Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn.

10. Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀.

11. A o rẹ̀ ìwo giga enia silẹ, a o si tẹ̀ ori igberaga enia ba, Oluwa nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na.

12. Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rẹ̀ silẹ.

13. Lori gbogbo igi kedari Lebanoni, ti o ga, ti a sì gbe soke, ati lori gbogbo igi-nla Baṣani.

14. Ati lori gbogbo òke giga, ati lori gbogbo òke kékèké ti a gbe soke.

15. Ati lori gbogbo ile-iṣọ giga ati lori gbogbo odi,

16. Ati lori gbogbo ọkọ̀ Tarṣiṣi, ati lori gbogbo awòran ti o wuni,

17. A o si tẹ̀ ori igberaga enia balẹ, irera awọn enia li a o si rẹ̀ silẹ; Oluwa nikanṣoṣo li a o gbega li ọjọ na.

18. Awọn òriṣa ni yio si parun patapata.

19. Nwọn o si wọ̀ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ìbẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀, nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.

Isa 2