Isa 16:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ẹ rán ọdọ-agutan si alakoso ilẹ lati Sela wá si aginju, si oke ọmọbinrin Sioni.

2. Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni.

3. Ẹ gbìmọ, ẹ mu idajọ ṣẹ; ṣe ojiji rẹ bi oru li ãrin ọsángangan; pa awọn ti a le jade mọ́; máṣe fi isánsa hàn.

Isa 16