Isa 13:13-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.

14. Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀.

15. Ẹnikẹni ti a ri li a o gun li agunyọ; ẹnikẹni ti o si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ wọn yio ti ipa idà ṣubu.

16. Ọmọ wọn pẹlu li a o fọ́ tũtu loju ara wọn; a o si kó wọn ni ile, a o si fi agbara bà obinrin wọn jẹ́;

17. Kiyesi i, emi o gbe awọn ara Media dide si wọn, ti ki yio ka fadakà si; bi o si ṣe ti wura, nwọn ki yio ni inu didùn si i.

18. Ọrun wọn pẹlu yio fọ́ awọn ọdọmọkunrin tũtũ; nwọn ki yio ṣãnu fun ọmọ-inu: oju wọn kì yio dá ọmọde si.

19. Ati Babiloni, ogo ijọba gbogbo, ẹwà ogo Kaldea, yio dabi igbati Ọlọrun bi Sodomu on Gomorra ṣubu.

20. A kì yio tẹ̀ ẹ dó mọ, bẹ̃ni a kì yio si gbe ibẹ̀ mọ lati irandiran: bẹ̃ni awọn ara Arabia kì yio pagọ nibẹ mọ; bẹ̃ni awọn oluṣọ-agutan kì yio kọ́ agbo wọn nibẹ mọ.

21. Ṣugbọn ẹranko igbẹ yio dubulẹ nibẹ; ile wọn yio si kun fun òwiwí, abo ogòngo yio ma gbe ibẹ, ọ̀rọ̀ yio si ma jo nibẹ.

Isa 13