Isa 13:10-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitori awọn iràwọ ọrun, ati iṣùpọ iràwọ inu rẹ̀ kì yio tàn imọlẹ wọn: õrun yio ṣu okùnkun ni ijadelọ rẹ̀, oṣùpa kì yio si mu ki imọlẹ rẹ̀ tàn.

11. Emi o si bẹ̀ ibi wò lara aiye, ati aiṣedẽde lara awọn enia buburu; emi o si mu ki igberaga awọn agberaga ki o mọ, emi o si mu igberaga awọn alagbara rẹ̀ silẹ.

12. Emi o mu ki ọkunrin kan ṣọwọ́n ju wura lọ; ani enia kan ju wura Ofiri daradara.

13. Nitorina emi o mu ọrun mì titi, ilẹ aiye yio si ṣipò rẹ̀ pada, ninu ibinu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ati li ọjọ ibinu gbigbona rẹ̀.

14. Yio si dabi abo agbọ̀nrin ti a nlepa, ati bi agutan ti ẹnikan kò gbajọ: olukuluku wọn o yipada si enia rẹ̀, olukuluku yio si sa si ilẹ rẹ̀.

Isa 13