13. Ilara Efraimu yio si tan kuro; Efraimu ki yio ṣe ilara Juda, Juda ki yio si bà Efraimu ninu jẹ.
14. Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ̀-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ilà-õrun jẹ: nwọn o si gbe ọwọ́ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ́.
15. Oluwa yio si pa ahọn okun Egipti run tũtũ; ẹfũfu lile rẹ̀ ni yio si mì ọwọ́ rẹ̀ lori odo na, yio si lù u ni iṣàn meje, yio si jẹ ki enia rekọja ni batà gbigbẹ.