Isa 10:9-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Kalno kò ha dabi Karkemiṣi? Hamati kò ha dabi Arpadi? Samaria kò ha dabi Damasku?

10. Gẹgẹ bi ọwọ́ mi ti nà de ijọba ere ri, ere eyi ti o jù ti Jerusalemu ati ti Samaria lọ.

11. Bi emi ti ṣe si Samaria ati ere rẹ̀, emi kì yio ha ṣe bẹ̃ si Jerusalemu ati ere rẹ̀ bi?

12. Nitorina yio si ṣe, nigbati Oluwa ti ṣe gbogbo iṣẹ rẹ̀ lori òke Sioni ati Jerusalemu, emi o ba eso aiya lile ọba Assiria wi, ati ogo ìwo giga rẹ̀.

13. Nitori o wipe, nipa agbara ọwọ́ mi ni emi ti ṣe e, ati nipa ọgbọ́n mi; nitori emi moye, emi si ti mu àla awọn enia kuro, emi si ti ji iṣura wọn, emi si ti sọ awọn ará ilu na kalẹ bi alagbara ọkunrin.

14. Ọwọ́ mi si ti wá ọrọ̀ awọn enia ri bi itẹ ẹiyẹ: ati gẹgẹ bi ẹnipe ẹnikan nko ẹyin ti o kù, li emi ti kó gbogbo aiye jọ; kò si ẹniti o gbọ̀n iyẹ, tabi ti o ya ẹnu, tabi ti o dún.

15. Ãke ha le fọnnu si ẹniti nfi i la igi? tabi ayùn ha le gbe ara rẹ̀ ga si ẹniti nmì i? bi ẹnipe ọgọ le mì ara rẹ̀ si awọn ti o gbe e soke, tabi bi ẹnipe ọpa le gbe ara rẹ̀ soke, bi ẹnipe ki iṣe igi.

16. Nitorina ni Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio mu awọn tirẹ̀ ti o sanra di rirù: ati labẹ ogo rẹ̀ yio da jijo kan bi jijo iná.

17. Imọlẹ Israeli yio si jẹ iná, ati Ẹni-Mimọ́ rẹ̀ yio jẹ ọwọ́-iná: yio si jo ẹgún ati ẹwọn rẹ̀ run, li ọjọ kan;

18. Yio si jo ogo igbó rẹ̀ run, ati oko rẹ̀ ẹlẹtù loju, ati ọkàn ati ara: nwọn o si dabi igbati ọlọpagun ndakú.

19. Iyokù igi igbó rẹ̀ yio si jẹ diẹ, ti ọmọde yio le kọwe wọn.

20. Yio si ṣe li ọjọ na, iyokù Israeli, ati iru awọn ti o salà ni ile Jakobu, ki yio tun duro tì ẹniti o lù wọn mọ; ṣugbọn nwọn o duro tì Oluwa, Ẹni-Mimọ Israeli, li otitọ.

21. Awọn iyokù yio pada, awọn iyokù ti Jakobu, si Ọlọrun alagbara.

22. Bi Israeli enia rẹ ba dàbi iyanrìn okun, sibẹ iyokù ninu wọn o pada: aṣẹ iparun na yio kun àkúnwọ́sílẹ̀ ninu ododo.

23. Nitori Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe iparun, ani ipinnu, li ãrin ilẹ gbogbo.

24. Nitorina bayi li Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Ẹnyin enia mi ti ngbe Sioni, ẹ má bẹ̀ru awọn ara Assiria: on o fi ọgọ lù ọ, yio si gbe ọpa rẹ̀ soke si ọ, gẹgẹ bi iru ti Egipti.

25. Ṣugbọn niwọn igba diẹ kiun, irunú yio si tan, ati ibinu mi ninu iparun wọn.

26. Oluwa awọn ọmọ-ogun yio gbe paṣan kan soke fun u, gẹgẹ bi ipakupa ti Midiani ni apata Orebu: ati gẹgẹ bi ọgọ rẹ̀ soju okun, bẹ̃ni yio gbe e soke gẹgẹ bi iru ti Egipti.

27. Yio si ṣe li ọjọ na, ni a o gbe ẹrù rẹ̀ kuro li ejika rẹ, ati àjaga rẹ̀ kuro li ọrùn rẹ, a o si ba àjaga na jẹ ní ọrùn rẹ.

28. On de si Aiati, on ti kọja si Migroni; ni Mikmaṣi li on ko ẹrù-ogun rẹ̀ jọ si:

Isa 10