2. Sam 8:4-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Dafidi si gbà ẹgbẹrun kẹkẹ lọwọ rẹ̀, ati ẹ̃dẹgbẹrin ẹlẹṣin, ati ẹgbãwa awọn ẹlẹsẹ: Dafidi si ja gbogbo ẹṣin kẹkẹ́ wọn wọnni ni pátì, ṣugbọn o da ọgọrun kẹkẹ́ si ninu wọn.

5. Nigbati awọn ara Siria ti Damasku si wá lati ran Hadadeseri ọba Soba lọwọ, Dafidi si pa ẹgbãmọkanla enia ninu awọn ara Siria.

6. Dafidi si fi awọn ologun si Siria ti Damasku: awọn ara Siria si wa sìn Dafidi, nwọn a si ma mu ẹbùn wá. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.

7. Dafidi si gbà aṣà wura ti o wà lara awọn iranṣẹ Hadadeseri, o si ko wọn wá si Jerusalemu.

8. Lati Beta, ati lati Berotai, awọn ilú Hadadeseri, ni Dafidi ọba si ko ọ̀pọlọpọ idẹ wá.

9. Nigbati Toi ọba Hamati si gbọ́ pe Dafidi ti pa gbogbo ogun Hadadeseri,

10. Toi si ran Joramu ọmọ rẹ̀ si Dafidi ọba, lati ki i, ati lati sure fun u, nitoripe o ti ba Hadadeseri jagun, o si ti pa a: nitoriti Hadadeseri sa ti ba Toi jagun. Joramu si ni ohun elo fadaka, ati ohun elo wura, ati ohun elo idẹ li ọwọ́ rẹ̀:

2. Sam 8