2. Sam 8:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Dafidi si ni asiki gidigidi nigbati o pada wá ile lati ibi pipa awọn ara Siria li afonifoji iyọ̀, awọn ti o pa jẹ ẹgbãsan enia.

14. O si fi awọn ologun si Edomu; ati ni gbogbo Edomu yika li on si fi ologun si, gbogbo awọn ti o wà ni Edomu si wá sin Dafidi. Oluwa si pa Dafidi mọ nibikibi ti o nlọ.

15. Dafidi si jọba lori gbogbo Israeli; Dafidi si ṣe idajọ ati otitọ fun awọn enia rẹ̀.

16. Joabu ọmọ Seruia li o si nṣe olori ogun; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi si nṣe akọwe.

17. Ati Sadoku ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki ọmọ Abiatari, li awọn alufa; Seruia a si ma ṣe akọwe.

18. Benaiah ọmọ Jehoiada li o si nṣe olori awọn Kereti, ati awọn Peleti; awọn ọmọ Dafidi si jẹ alaṣẹ.

2. Sam 8