9. Dafidi si joko ni ile awọn ọmọ-ogun ti o ni odi, a si npè e ni ilu Dafidi. Dafidi mọ ògiri yi i ka lati Millo wá, o si kọ ile ninu rẹ̀.
10. Dafidi si npọ̀ si i, Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun si wà pẹlu rẹ̀.
11. Hiramu ọba Tire si rán awọn iranṣẹ si Dafidi, ati igi kedari, ati awọn gbẹnàgbẹnà, ati awọn ti ngbẹ́ okuta ogiri: nwọn si kọ́ ile kan fun Dafidi.
12. Dafidi si kiyesi i pe, Oluwa ti fi idi on mulẹ lati jọba lori Israeli, ati pe, o gbe ijọba rẹ̀ ga nitori Israeli awọn enia rẹ̀.
13. Dafidi si tun mu awọn alè ati aya si i lati Jerusalemu wá, lẹhin igbati o ti Hebroni bọ̀: nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin fun Dafidi.
14. Eyi si ni orukọ awọn ti a bi fun u ni Jerusalemu, Ṣammua ati Ṣobabu, ati Natani, ati Solomoni,