1. NIGBATI ọmọ Saulu si gbọ́ pe Abneri kú ni Hebroni, ọwọ́ rẹ̀ si rọ, gbogbo Israeli si rẹ̀wẹsi.
2. Ọmọ Saulu si ni ọkunrin meji ti iṣe olori ẹgbẹ ogun: a npe orukọ ọkan ni Baana, ati orukọ keji ni Rekabu, awọn ọmọ Rimmoni ara Beeroti ti awọn ọmọ Benjamini: (nitoripe a si ka Beeroti pẹlu Benjamini:
3. Awọn ara Beeroti si ti sa lọ si Gittaimu, nwọn si ṣe atipo nibẹ titi o fi di ọjọ oni yi.)