2. Kro 8:13-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.

14. O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ.

15. Nwọn kò si yà kuro ninu ilana ọba nipa ti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi niti olukuluku ọ̀ran, ati niti iṣura.

2. Kro 8