2. Kro 6:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Njẹ nisisiyi, Oluwa, Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa eyi ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́, wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ́ Israeli: kiki bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati ma rìn ninu ofin mi, bi iwọ ti rìn niwaju mi.

17. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o ṣẹ, ti iwọ ti sọ fun Dafidi, iranṣẹ rẹ,

18. Ni otitọ ni Ọlọrun yio ha ma ba enia gbe li aiye? Kiyesi i, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọsi ile yi ti emi kọ́!

19. Sibẹ, iwọ ṣe afiyesi adura iranṣẹ rẹ, ati ẹ̀bẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati adura ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ:

20. Ki oju rẹ ki o le ṣí si ile yi lọsan ati loru, ani si ibi ti iwọ ti wipe, iwọ o fi orukọ rẹ sibẹ; lati tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ ngbà si ibi yi.

21. Nitorina gbọ́ ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati ti Israeli enia rẹ ti nwọn o ma gbà si ibi yi: iwọ gbọ́ lati ibugbe rẹ wá, ani lati ọrun wá, nigbati iwọ ba gbọ́, ki o si dariji.

22. Bi ọkunrin kan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, ti ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi;

2. Kro 6