3. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pejọ sọdọ ọba li ajọ, eyi ni oṣù keji.
4. Gbogbo awọn àgbagba Israeli si wá; awọn ọmọ Lefi si gbé apoti-ẹri na.
5. Nwọn si gbé apoti-ẹri na gòke, ati agọ ajọ, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ, wọnyi ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi mu gòke wá.
6. Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀, wà niwaju apoti-ẹrí na, nwọn si fi agutan ati malu rubọ, ti a kò le kà, bẹ̃ni a kò le mọ̀ iye wọn fun ọ̀pọlọpọ.
7. Awọn alufa si gbé apoti-ẹri ti majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀, si ibi-idahùn ile na, sinu ibi-mimọ́-jùlọ, labẹ iyẹ awọn kerubu:
8. Bẹ̃ni awọn kerubu nà iyẹ wọn bò ibi apoti-ẹri na, awọn kerubu si bò apoti-ẹri na, ati awọn ọpa rẹ̀ lati òke wá.
9. Ọpa rẹ̀ wọnni si gùn tobẹ̃, ti a fi ri ori awọn ọpa na lati ibi apoti-ẹri na niwaju ibi mimọ́-jùlọ na, ṣugbọn a kò ri wọn li ode. Nibẹ li o si wà titi di oni yi.